Mark 1:35-38

Jesu ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti gbàdúrà

35 aNí kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. 36Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. 37Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”

38Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”
Copyright information for YorBMYO